Numbers 3:21-37


21Ti Gerṣoni ni ìdílé Libni àti Ṣimei; àwọn ni ìdílé Gerṣoni.
22Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500).
23Àwọn ìdílé Gerṣoni yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀-oòrùn lẹ́yìn àgọ́.
24Olórí àwọn ìdílé Gerṣoni ni Eliasafu ọmọ Láélì.
25Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gerṣoni nínú àgọ́ ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

27Ti Kohati ní ìdílé Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli, wọ̀nyí ni ìran Kohati.
28Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rin ó-lé-ẹgbẹ̀ta (8,600),
tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́.
29Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.
30Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli.
31Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.
32Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.

33Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari.
34Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).
35Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili.
Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.
36Àwọn ìran Merari ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn; 37Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.
Copyright information for YorBMYO